62. Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Ísírẹ́lì rú ẹbọ níwájú Olúwa.
63. Sólómónì rú ẹbọ ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbàá mọ́kànlá (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn omọ Ísírẹ́lì ya ilé Olúwa sí mímọ́.
64. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárin tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ọrẹ ṣíṣun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.