nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.