Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjìn.