1 Ọba 5:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Báyìí ni Hírámù sì pèsè igi Kédárì àti igi fírì tí Sólómónì ń fẹ́ fún un,

11. Sólómónì sì fún Hírámù ní ẹgbàawá (20,000) òṣùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún (20) òṣùwọ̀n òróró dáradára. Sólómónì sì ń tẹ̀ṣíwájú láti ṣe èyí fún Hírámù lọ́dọọdún.

12. Olúwa sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrin Hírámù àti Sólómónì, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.

13. Sólómónì ọba sì sa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Ísírẹ́lì; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ènìyàn (30,000).

14. Ó sì rán wọn lọ sí Lébánónì, ẹgbàárún (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lébánónì, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Ádónírámù ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.

15. Sólómónì sì ní ẹgbàá márùndínlógójì (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè,

16. àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Sólómónì jẹ́ ẹgbẹ̀rindínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà.

1 Ọba 5