1. Sólómónì ọba sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.
2. Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀:Ásáríyà ọmọ Ṣádókù àlùfáà:
3. Élíhóréfù àti Áhíjà àwọn ọmọ Ṣísánì akọ̀wé;Jèhósáfátì ọmọ Áhílúdì ni akọ̀wé ìlú;
4. Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni olórí ogun;Sádókù àti Ábíátarì ni àwọn àlùfáà;
5. Ásáríyà ọmọ Nátanì ni olórí àwọn agbègbè;Sóbúdù ọmọ Nátanì, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn;
6. Áhísárì ni olùtọ́jú ààfin;Ádónírámù ọmọ Ábídà ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú
7. Sólómónì sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.
8. Orúkọ wọn ni wọ̀nyí:Bénhúrì ní ìlú olókè Éfúráímù.
9. Beni-Dékérì ní Mákásì, Ṣáíbímù, Bẹti-Sémésì, àti Eloni-Bétíhánánì;
10. Beni-Hésédì, ní Árúbótì; tirẹ̀ ni Sókò àti gbogbo ilẹ̀ Héférì ń ṣe;
11. Beni-Ábínádábù, ní Napoti Dórì; òun ni ó fẹ́ Táfátì ọmọbìnrin Sólómónì ní aya.
12. Báánà ọmọ Áhílúdì, ní Táánákì àti Mégídò, àti ní gbogbo Bétísánì tí ń bẹ níhà Saritanà níṣàlẹ̀ Jésérẹ́lì, láti Bétísánì dé Abeli-Méhólà títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jókínéámù;
13. Bẹni-Gébérì ní Rámótì-Gílíádì; tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jáírì ọmọ Mànásè tí ń bẹ ní Gílíádì, tirẹ̀ sì ni agbégbé Ágóbù, tí ń bẹ ní Básánì, ọgọ́ta (60) ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin.
14. Áhínádábù ọmọ Ídò ní Máhánáímù
15. Áhímásì ní Náfítalì; ó fẹ́ Básémátì ọmọbìnrin Sólómónì ní aya;
16. Báánà ọmọ Húṣáì ní Ásérì àti ní Álótì;
17. Jèhósáfátì ọmọ Párúhà ni ó wà ní Ísákárì;
18. Síméì ọmọ Élà ni Bẹ́ńjámínì;
19. Gébérì ọmọ Úrì ní Gílíádì; orílẹ̀ èdè Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì àti orílẹ̀ èdè Ógù ọba Básánì. Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.
20. Àwọn ènìyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.