1. Sólómónì sì bá Fáráò ọba Éjíbítì dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú-un wá sí ìlú Dáfídì títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹ́ḿpìlì Olúwa, àti odi tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká.
2. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tíì kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa títí di ìgbà náà
3. Sólómónì sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dáfídì baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga.
4. Ọba sì lọ sí Gíbíónì láti rúbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Sólómónì sì rú ẹgbẹ̀rún ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.