8. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Áhábù, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Nábótì pẹ̀lú rẹ̀.
9. Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé:“Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn.
10. Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú ṣíwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí pa á wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.”
11. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí wọ́n ń ṣe ará ìlú Nábótì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésébélì ti ránṣẹ́ sí wọn.
12. Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, wọ́n sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn.
13. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó ṣíwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí pa Nábótì níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Nábótì ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.
14. Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jésébélì wí pé: “A ti sọ Nábótì ní òkúta, ó sì kú.”
15. Bí Jésébélì sì ti gbọ́ pé, a ti sọ Nábótì ní Òkúta pa, ó sì wí fún Áhábù pé, “Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà Nábótì, ará Jésérẹ́lì, tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láàyè mọ́, ó ti kú.”
16. Nígbà tí Áhábù sì gbọ́ pé Nábótì ti kú, ó sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún ọgbà àjàrà Nábótì.
17. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà ará Tíṣíbì wá wí pé;
18. “Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Áhábù ọba Ísírẹ́lì, tí ó wà ní Samáríà. Ó wà ní ọgbà àjàrà Nábótì báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀.
19. Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ”
20. Áhábù sì wí fún Èlíjà pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀ta mi!”Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa.
21. ‘Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ. Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ Áhábù gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní Ísírẹ́lì.
22. Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jéróbóámù, ọmọ Nébátì, àti bí ilé Bááṣà, ọmọ Áhíjà, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.’
23. “Àti níti Jésébélì pẹ̀lú Olúwa wí pé: ‘Àwọn ajá yóò jẹ Jésébélì nínú yàrá Jésírẹ́lì.’