1 Ọba 21:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Jésébélì aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Ísírẹ́lì? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésérẹ́lì.”

8. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Áhábù, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Nábótì pẹ̀lú rẹ̀.

9. Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé:“Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn.

1 Ọba 21