11. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí wọ́n ń ṣe ará ìlú Nábótì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésébélì ti ránṣẹ́ sí wọn.
12. Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, wọ́n sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn.
13. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó ṣíwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí pa Nábótì níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Nábótì ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.
14. Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jésébélì wí pé: “A ti sọ Nábótì ní òkúta, ó sì kú.”
15. Bí Jésébélì sì ti gbọ́ pé, a ti sọ Nábótì ní Òkúta pa, ó sì wí fún Áhábù pé, “Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà Nábótì, ará Jésérẹ́lì, tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láàyè mọ́, ó ti kú.”