1 Ọba 18:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Èlíjà sì wí pé, “Bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, ní tòótọ́ èmi yóò fi ara mi hàn fún Áhábù lónìí.”

16. Bẹ́ẹ̀ ni Ọbadíà sì lọ láti pàdé Áhábù, ó sì sọ fún un, Áhábù sì lọ láti pàdé Èlíjà.

17. Nígbà tí ó sì rí Èlíjà, ó sì wí fún un pé, “Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu?”

18. Èlíjà sì dá a lóhùn pé, “Èmi kò yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé bàbá rẹ. Ẹ ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Báálímù lẹ́yìn.

19. Nísinsìn yìí kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti pàdé mi lórí òkè Kámẹ́lì. Àti kí o sì mú àádọ́tàlénírinwó (450) àwọn wòlíì Báálì àti irinwó (400) àwọn wòlíì ère òrìṣà tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jésébélì.”

20. Bẹ́ẹ̀ ni Áhábù ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì kó àwọn wòlíì jọ sí orí òkè Kámẹ́lì.

21. Èlíjà sì lọ ṣíwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì? Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan.

22. Nígbà náà ni Èlíjà wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa, ṣùgbọ́n, àádọ́tàlénírinwó (450) ni wòlíì Báálì.

23. Ẹ fún wa ní ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì ké e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i.

24. Nígbà náà ẹ ó sì képe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì képe orúkọ Olúwa. Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run.”Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára.”

1 Ọba 18