1 Ọba 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù ọmọ Nébátì, Ábíjà jọba lórí Júdà,

2. ó sì jọba ní ọdún mẹ́ta ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù.

3. Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀; ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbáńlá rẹ̀ ti ṣe.

4. Ṣùgbọ́n, nítorí i Dáfídì Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jérúsálẹ́mù nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀.

1 Ọba 15