22. Bí ó sì ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Nátanì wòlíì sì wọlé.
23. Wọ́n sì sọ fún ọba pé, “Nátanì wòlíì wà níbí.” Ó sì lọ ṣíwájú ọba, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀.
24. Nátanì sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ, Olúwa mi ọba, ti sọ pé Àdóníjà ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn rẹ àti pé òun ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ?
25. Ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ ní òní, ó sì ti rúbọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran ọlọ́ràá àti àgùntàn. Ó sì ti pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, Balógun àti Ábíátarì àlùfáà. Ní sinsin yìí wọ́n ń jẹ wọ́n ń mu pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Kí Àdóníjà ọba kí ó pẹ́!’
26. Ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́ rẹ, àti ṣádókù àlùfáà, àti Bẹ́náyà ọmọ Jéhóiádà, àti Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ ni kò pè.