1. Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí fi fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.
2. Ní ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀, kí olukúlúkù yín fí sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.
3. Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jérúsálẹ́mù.
4. Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.
5. Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrin Makedóníà: nítorí èmi yóò kọjá láàrin Makedóníà.
6. Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbi kí n tílẹ̀ lo àkókò òtúútúú, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ.
7. Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọja lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́
8. Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Éfésù títí dí Pẹ́ńtíkósìtì.
9. Nítorí pé ilẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣi sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀ta tí ń bẹ.