1 Kọ́ríńtì 16:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí fi fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.

2. Ní ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀, kí olukúlúkù yín fí sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.

3. Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jérúsálẹ́mù.

4. Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.

1 Kọ́ríńtì 16