1 Kọ́ríńtì 15:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àti pé ó farahàn Pétérù, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá

6. Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fí di ìsinsìnyìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn.

7. Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jèmísì; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn Àpósítélì.

8. Àti níkẹyín gbogbo wọn ó fáráhàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.

9. Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn àpósítélì, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní àpósítélì, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run.

10. Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fí fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ̀pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.

11. Nítorí náà ìbáà ṣe èmí tabí àwọn ni, bẹ́ẹ̀ ní àwa wàásù, bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́

12. Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kírísítì pé ó tí jíǹdé kúró nínú òkú, è é há tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín ti wí pé, àjíǹde òkú kò sí.

13. Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kírísítì kò jíǹde.

1 Kọ́ríńtì 15