37. Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tabí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkán wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé ofin Olúwa ni wọ́n.
38. Ṣùgbọ́n bí ẹnikan bá fi ojú fo èyí dá, òun fún ra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.
39. Nítorí náà ará, ẹ máa fí ìtara ṣáfẹrí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dànílẹ́kún láti fi èdè fọ̀.
40. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.