1 Kọ́ríńtì 14:30-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Bí a bá sì fí ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́.

31. Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ́kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú.

32. Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì.

33. Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà.Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ijọ ènìyàn mímọ́

34. Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ijọ: nítorí a kò fí fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ ki wọn wà lábẹ́ itẹríbá, bí ó ṣe rí ni gbogbo àpéjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

35. Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn bèèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.

1 Kọ́ríńtì 14