1 Kọ́ríńtì 14:15-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ǹjẹ́ kín ni èmi ó ṣe? Èmí o fí ẹ̀mí mí gbàdúrà, èmi ó sí fí ọkàn gbàdúrà pẹ̀lú: Èmi ó fi ẹ̀mí kọrin, èmi o sí fi ọkàn kọrin pẹ̀lú.

16. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá sú ìre nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ́ wí?

17. Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítóótọ́, ṣùgbọ́n a kó fí ẹsẹ̀ ẹnikéjì rẹ múlẹ̀.

18. Mó dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run tí èmi ń fọ̀ onírúurú èdè ju gbogbo yín lọ:

19. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fí ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹ̀lomíran ju ẹgbáarún ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀.

20. Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà.

21. A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,“Nípa àwọn aláhọ́n mìírànàti elété mìírànní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”ni Olúwa wí.

22. Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n isọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23. Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fí èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ̀kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹyin ń ṣe òmùgọ̀?

24. Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbi tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀.

25. Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi aṣiri ọkan rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sín Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrin yín!”

1 Kọ́ríńtì 14