1 Kọ́ríńtì 11:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Nítorí nígbákùúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú kọ́ọ̀bù yìí, ni ẹ tún sọ nipa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

27. Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú kọ́ọ̀bù Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.

28. Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa kí ó tó jẹ lára àkàrà nàá àti kí ó tó mu nínú ife náà.

1 Kọ́ríńtì 11