1 Kọ́ríńtì 10:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rúbọ wọn sí àwọn ẹ̀mí èsù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù.

21. Ẹ̀yin kò lè mu nínú kọ́ọ́bù tí Olúwa àti kọ̀ọ́bù ti èṣù lẹ̀ẹ́kan náà. Ẹ kò lè jẹun ní tábìlì Olúwa kí ẹ tún jẹ tábìlì ẹ̀mí èsù lẹ́ẹ̀kan náà.

22. Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe? Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí? Àwa ha ní agbára jù ú lọ?

1 Kọ́ríńtì 10