11. Gbogbo àwọn nǹkan tí mo ń wí wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n sì jẹ́ àpẹrẹ, fún wa, wọ́n kọ wọ́n sílẹ̀ bí ikìlọ̀ fún wa láti yàgò kúrò nínú síṣe àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. A kọ èyí sílẹ̀ fún kíkà wa ní àkókò yìí tí aye fi ń lọ sópin.
12. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à subú.
13. Kò sí ìdànwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó ti bá ènìyàn rí, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlórun, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ̀n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ́yin baà lè faradà á.
14. Nítorí náà, ẹ̀yín olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.
15. Èmi ń sọ̀rọ̀ sí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnra rẹ̀ ohun tí mo sọ.
16. Ago ìbùkún tí a ń súre sí, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kírísítì bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín nínú ara Kírísítì bi?
17. Bí ó ti wù kí ènìyàn pọ̀ níbẹ́ tó, gbogbo wa ní ń jẹ lára àkàrà ẹyọkan ṣoṣo náà Eléyìí fi hàn wá pé gbogbo wá jẹ́ ẹ̀yà ara kan.
18. Ẹ wo Ísírẹ́lì nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha se alábàápín pẹpẹ bí?
19. Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rubọ sí òrìsà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìsà jẹ́ nǹkan kan?
20. Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rúbọ wọn sí àwọn ẹ̀mí èsù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù.
21. Ẹ̀yin kò lè mu nínú kọ́ọ́bù tí Olúwa àti kọ̀ọ́bù ti èṣù lẹ̀ẹ́kan náà. Ẹ kò lè jẹun ní tábìlì Olúwa kí ẹ tún jẹ tábìlì ẹ̀mí èsù lẹ́ẹ̀kan náà.
22. Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe? Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí? Àwa ha ní agbára jù ú lọ?