1 Kọ́ríńtì 1:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ará, ẹ kíyèsí ohun tí nígbà tí a pè yín. Bí ó ti ṣe pé, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn nípa ti ara, kí í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà, kì ì ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́lá ni a pè.

27. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára.

28. Ó ti yan ètò tí ayé kẹ́gàn, tí wọn kò kà sí rárá, láti sọ nǹkan tí wọ́n kà sí ńlá di ohun asán àti aláìwúlò.

29. Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.

1 Kọ́ríńtì 1