7. Námánì Áhíjà àti Gérà, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Úṣà àti Áhíhúdù.
8. A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣáháráímù ní Móábù lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó Rẹ̀ sílẹ̀, Húṣímù àti Báárà.
9. Nípaṣẹ̀ ìyàwó Rẹ̀ Hódéṣì ó ní Jóbábù ṣíbíà, Méṣà, Málíkámà,
10. Jéúṣì Ṣákíà àti Mírímà. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
11. Nípaṣẹ̀ Húṣímù ó ní Ábítúbù àti Élípálì.
12. Àwọn ọmọ Élípálì:Ébérì, Míṣámì, Ṣémédù (ẹni tí ó kọ́ Ónò àti Lódì pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká Rẹ̀.)