75. Húkokì àti Réhóbù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;
76. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Náfítalìwọ́n gba Kédésì ní Gálílì, Hámoníà Kíríátaímù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
77. Àwọn ará Mérárì (ìyókù àwọn ará Léfì) gbà nǹkan wọ̀nyí:Láti ẹ̀yà Sébúlúnìwọ́n gba Jókíneámù, Kárítahì, Rímónò àti Tábórì, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;