1 Kíróníkà 6:57-61 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

57. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì (ìlú ti ààbò), àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà,

58. Hílénì Débírì,

59. Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.

60. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀.

61. Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.

1 Kíróníkà 6