1 Kíróníkà 28:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Èmi yóò fi ìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí.

8. “Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsìn yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí Olúwa, àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa: Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé.

9. “Àti ìwọ, ọmọ mi Sólómónì, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn-ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ọ́ títí láé.

10. Gbèrò báyìí nítorí tí Olúwa ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún Olúwa. Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà.”

11. Nígbà náà, Dáfídì fún Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ní ètò fún èbúté ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ Rẹ̀, àwọn yàrá ìṣúra Rẹ̀, ibi òkè Rẹ̀, àwọn ìyẹ̀wù Rẹ̀ àti ibi ìpètù sí Rẹ̀.

12. Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn Rẹ̀ fún ti ààfin ilé Olúwa àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀.

13. Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn Rẹ̀.

14. Ó yàn ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà tí a ó lò níbi orísìí ìsìn, àti ìwọ̀n fàdákà fún gbogbo ohun èlò fàdákà tí a ó lò fún oríṣìí ìsìn:

15. Ìwọ̀n wúrà fún ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn, fún ìwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn; àti ìwọ̀n fàdákà ìdúró fìtilà fàdákà àti àwọn fìtílà Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlò ti gbogbo ìduró fìtílà.

16. Ìwọ̀n ti wúrà fun tabílì, tabílì fún àkàrà tí a yà sọ́tọ̀; ìwọ̀n fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà;

1 Kíróníkà 28