1 Kíróníkà 27:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Jóábù ọmọ Ṣérúyà bẹ̀rẹ̀ sí ní kàwọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Ísírẹ́lì nipaṣẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọọ́ sínu ìwé ìtàn ayé ti ọba Dáfídì.

25. Áṣímáfétì ọmọ Ádíélì wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jónátanì ọmọ Úṣíà wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìlètò àti àwọn ilé ìṣọ́.

26. Ésírì ọmọ kélúbì wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.

1 Kíróníkà 27