1 Kíróníkà 26:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Àwọn ará Léfì mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúṣù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.

18. Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnrarẹ̀.

19. Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ ti kórà àti Mérà.

20. Àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Léfì wọn wà ní ìdí ilé ìfowópamọ́ sí ti ile Ọlọ́run àti ilé ohun èlò yíyà sọ́tọ̀.

1 Kíróníkà 26