1 Kíróníkà 26:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà gúṣù bọ́ sí ọ̀dọ̀ Obedì Édómù, kèké fún ilé ìṣúra sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ ọmọ Rẹ̀.

16. Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣálélà-etí ẹnu ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣúpímì àti Hósà.Olùsọ́ wà ní ẹ̀bá Olùsọ́:

17. Àwọn ará Léfì mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúṣù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.

18. Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnrarẹ̀.

1 Kíróníkà 26