1. Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Árónì:Àwọn ọmọ Árónì ni Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì.
2. Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; Bẹ́ẹ̀ ni Élíásérì àti Ítamárì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
3. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ṣádókì ọmọ Élíásérì àti Áhímélékì ọmọ Ítamárì, Dáfídì sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.