27. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì sí, àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
28. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ni láti ran àwọn ọmọ Árónì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tìí ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.
29. Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ ọrẹ, àti aláìwú pẹ̀tẹ̀, àti fún dídùn àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùnwọ̀n.
30. Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àsálẹ́.