1 Kíróníkà 23:11-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Jáhátì sì ni alákọ́kọ́ Ṣísà sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jéúsì àti Béríà kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.

12. Àwọn ọmọ kóhátì:Ámírámù, Ísárì, Hébúrónì àti Usíélì mẹ́rin ni gbogbo wọn.

13. Àwọn ọmọ Ámírámù.Árónì àti Móṣè.A sì ya Árónì sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ Rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rúbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjísẹ́ níwájú Rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ Rẹ̀ títí láéláé.

14. Àwọn ọmọ Mósè ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apákan ẹ̀yà Léfì.

15. Àwọn ọmọ Mósè;Gérísónì àti Élíásérì.

16. Àwọn ọmọ GérísónìṢúbáélì sì ni alákọ́kọ́.

17. Àwọn ọmọ Élíásérì:Réhábíà sì ni ẹni àkọ́kọ́.Élíásérì kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Réhábíà wọ́n sì pọ̀ níye.

18. Àwọn ọmọ Ísárì:Ṣélómítì sì ni ẹni àkọ́kọ́.

19. Àwọn ọmọ Hérónì:Jéríyà sì ni ẹni àkọ́kọ́, Ámáríyà sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jáhásíélì sì ni ẹ̀ẹ̀kẹta àti Jékáméámù ẹ̀ẹ̀kẹrin.

20. Àwọn ọmọ Húsíélì:Míkà ni àkọ́kọ́ àti Íṣíà ẹ̀ẹ̀kejì.

21. Àwọn ọmọ Mérárì:Máhílì àti Músì.Àwọn ọmọ Máhílì:Élíásárì àti Kísì.

22. Élíásérì sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kísì, sì fẹ́ wọn.

23. Àwọn ọmọ Músì:Málì, Édérì àti Jérímótì mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24. Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Léfì bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa

25. Nítorí pé Dáfídì ti sọ pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jérúsálẹ́mù títí láéláé.

26. Àwọn ọmọ Léfì kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn Rẹ̀.

27. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì sí, àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

28. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ni láti ran àwọn ọmọ Árónì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tìí ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.

29. Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ ọrẹ, àti aláìwú pẹ̀tẹ̀, àti fún dídùn àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùnwọ̀n.

1 Kíróníkà 23