1 Kíróníkà 21:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n Jóábù kó àwọn Léfì àti Bẹ́ńjámínì mọ́ iye wọn, nítorí àsẹ ọba jẹ́ ìríra fún un.

7. Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Ísírẹ́lì.

8. Nígbà náà Dáfídì sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidìgidì nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà òmùgọ̀ gidigidi.

9. Olúwa sì fi fún Gádì, aríran Dáfídì pé.

10. “Lọ kí o lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Èyí ní ohun tí Olúwa sọ: Èmi sì fún ọ ní àwọn àṣàyàn mẹ́ta. Yan ọ̀kan ninú wọn fún mi láti gbé jáde nípa rẹ.’ ”

1 Kíróníkà 21