4. Ọ̀rọ̀ ọba, bí ó ti wù kí ó rí, borí tí Jóábù. Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù kúrò ó sì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù.
5. Jóábù sì sọ iye tí àwọn ajagun ọkùnrin náà jẹ́ fún Dáfídì. Ní gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì jásí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (Mílíọnù kan àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún) tí ó lè mú idà àti pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́talélógún lé ẹgbàrún ní Júdà.
6. Ṣùgbọ́n Jóábù kó àwọn Léfì àti Bẹ́ńjámínì mọ́ iye wọn, nítorí àsẹ ọba jẹ́ ìríra fún un.
7. Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Ísírẹ́lì.
8. Nígbà náà Dáfídì sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidìgidì nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà òmùgọ̀ gidigidi.