1 Kíróníkà 2:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. (Ṣùgbọ́n Gésúrì àti Árámù sì fi agbára gba Hafoti Jáírì, àti Kénátì pẹ̀lú gbogbo agbégbé Rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Mákírì Baba Gílíádì.

24. Lẹ́yìn tí Hésírónì sì kú ni Kélẹ́bù Éfúrátà, Ábíà ìyàwó Rẹ̀ ti Hésírónì sì bí Áṣúrì baba Tẹ́kóà fún un

25. Ọmọ Jéráhímélì àkọ́bí Hésírónì:Rámà ọmọ àkọ́bí Rẹ̀ Búnà, Órénì, óṣémù àti Áhíjà.

1 Kíróníkà 2