8. Ní gbígbọ́ eléyìí, Dáfídì rán Jóábù jáde pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun ọkùnrin tí ó le jà.
9. Àwọn ará Ámónì jáde wá, wọ́n sì dá isẹ́ ogun ní àbáwọlé sí ìlú ńlá wọn, nígbà tí àwọn ọba tí ó wá, fún rara wọn wà ni orílẹ̀ èdè tí ó sí sílẹ̀.
10. Jóábù ri wí pé àwọn ìlà ogun wà níwájú àti ẹ̀yìn òun; Bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ogun tí ó dára ní Ísírẹ́lì, o sì tẹ́ ogun wọn sí àwọn ará Ṣíríà.
11. Ó fi ìyókù àwọn ọkùnrin náà sí abẹ́ àkóso Ábíṣáì arákùrin Rẹ̀, a sì tẹ́ wọn kí wọn dojúkọ àwọn ará Ámónì.
12. Jóábù wí pé Tí àwọn ará Ṣíríà bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; Ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ámónì bá le jù fún ọ, Nígbà náà èmi yóò gbà ọ́.