1. Ní àkókò yí, Náháṣì ọba àwọn ará Ámónì kú, ọmọ Rẹ̀ sì rọ́pò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
2. Dáfídì rò wí pé Èmi yóò fi inú rere hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, nítorí baba a Rẹ̀ fi inú-rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí Hánúnì níti baba a Rẹ̀.Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dáfídì wá sí ọ̀dọ̀ Hánúnì ní ilẹ̀ Àwọn ará Ámónì láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí i,
3. Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ámónì sọ fún Hánúnì pé, Ṣé ìwọ rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún Baba rẹ nípa rírán àwọn ọkùnrin sí ọ láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn.? Ṣé àwọn ọkùnrin Rẹ̀ kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti wá kiri àti samí sita orílẹ̀ èdè àti láti bì í ṣubú.