1 Kíróníkà 18:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà tí Tóù ọba Hámátì gbọ́ pé Dáfídì ti borí gbogbo ọmọ ogun Hádádéṣérì ọba Ṣóbà.

10. Ó rán ọmọ Rẹ̀ Ádórámì sí ọba Dáfídì láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun Rẹ̀ nínú ogun lórí Hádádéṣérì, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tóù. Ádórámì mú oríṣiríṣi ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti tan-gan-ran wá.

11. Ọba Dáfídì ya ohun èlò wọ̀n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí: Édómù àti Móábù, ará Ámónì àti àwọn ará Fílístínì àti Ámálékì.

12. Ábíṣáì ọmọ Ṣeruíà, lu méjìdínlógojì ẹgbẹ̀rin ará Édómù bolẹ̀ ní àfonífojì iyọ̀.

13. Ó fi Gárísónì sí Édómù, gbogbo àwọn ará Édómù sì ń sìn ní abẹ́ Dáfídì. Olúwa fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

1 Kíróníkà 18