1 Kíróníkà 17:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé.

5. Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.

6. Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi?” ’

1 Kíróníkà 17