11. Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀.
12. Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé.
13. Èmi yóò jẹ́ bàbá Rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kurò lọ́dọ̀ Rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo se mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú Rẹ̀.
14. Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ Rẹ̀ ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”