16. Ní àsìkò náà Dáfídì sì wà nínú ibi gíga àti àwọn ará Fílístínì modi sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
17. Dáfídì sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Áà, ẹnìkan yóò ha buomi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù fún un mu?
18. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Fílístínì, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó sì gbé padà tọ Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa.
19. “Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe se èyí!” ó wí pé. “Se kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dáfídì kò ní mu ú.Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.
20. Ábíṣáì arákùnrin Jóábù ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta.
21. Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.