47. Nígbà tí Hádádì sì kú, Ṣámílà láti Másírékà, ó sì jọba ní ipò Rẹ̀
48. Nígbà tí Ṣámílà sì kú, Ṣáúlì láti Réhóbótì lórí odò sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀
49. Nígbà tí Ṣáúlì sì kú, Báli-hánánì, ọmọ Ákíbórì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀.
50. Nígbà tí Báli-hánánì sì kú, Hádádì sì di ọba nípò Rẹ̀. Orúkọ ìlú Rẹ̀ sì ni Páì; àti orúkọ ìyàwó sì ni Méhélábélì ọmọbìnrin Métírédì, ọmọbìnrin Mésíhábù.