45. Nígbà tí Jóbábù sì kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀.
46. Nígbà tí Húṣámù sì kú, Hádádì ọmọ Bédádì, ẹni tí ó kọlu Mídíánì ní agbégbé Móábù, ó sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀. Orúkọ ìlú Rẹ̀ sì ni Áfítì.
47. Nígbà tí Hádádì sì kú, Ṣámílà láti Másírékà, ó sì jọba ní ipò Rẹ̀
48. Nígbà tí Ṣámílà sì kú, Ṣáúlì láti Réhóbótì lórí odò sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀
49. Nígbà tí Ṣáúlì sì kú, Báli-hánánì, ọmọ Ákíbórì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀.