6. Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jésù Kírísitì, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ̀rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí.
7. Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí.
8. Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan.
9. Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù: nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀.