1 Jòhánù 3:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Àti ohunkòhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkàn tí ó dára lójú rẹ̀.

23. Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jésù Kírísítì Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa.

24. Ẹni tí ó bá sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú rẹ̀. Àti nípa èyí ni àwa mọ̀ pé ó ń gbé inú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fi fún wa.

1 Jòhánù 3