1 Jòhánù 1:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kò sì sí nínú wa.

9. Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣododo gbogbo.

10. Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́sẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa.

1 Jòhánù 1