4. Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.
5. Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ tí àwa sì ń jẹ́ fún yín: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá.
6. Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́.
7. Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jésù Kírísítì, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kùrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo.
8. Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kò sì sí nínú wa.